Isaiah 44:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà igi yìí di igi ìdáná: Eniyan óo gé ninu rẹ̀, yóo fi dáná yá; yóo gé ninu rẹ̀ yóo fi dáná oúnjẹ; yóo gé ninu rẹ̀, yóo fi gbẹ́ ère, yóo máa bọ ọ́. Eniyan á wá sọ igi lásán tí ó gbẹ́ di oriṣa, á sì máa foríbalẹ̀ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni yio jẹ ohun idana fun enia: nitori yio mu ninu wọn, yio si fi yá iná; lõtọ, o dá iná, o si din akara, lõtọ, o ṣe ọlọrun fun ra rẹ̀, o si nsìn i; o gbẹ ẹ li ere, o si nforibalẹ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn; díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́, ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà. Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín; ó yá ère, ó sì ń forí balẹ̀ fún un.