Isaiah 44:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò sí ẹni tí ó ronú wò, tabi tí ó ní ìmọ̀ tabi òye, láti wí pé: “Ìdajì igi yìí ni mo fi dáná tí mo fi se oúnjẹ, tí mo sì fi se ẹran tí mo jẹ. Kí ló wá dé tí n óo ṣe fi ìyókù gbẹ́ ère kí n máa bọ ọ́? Ṣé ìtì igi lásán ló yẹ kí n máa foríbalẹ̀ fún, kí n máa bọ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si ẹniti o rò li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ni ko si imọ̀ tabi oye lati wipe, Mo ti fi apakan rẹ̀ da iná; mo si din akara pẹlu lori ẹyin iná rẹ̀: mo ti sun ẹran, mo si jẹ ẹ: emi o ha fi iyokù rẹ̀ ṣe irira? emi o ha foribalẹ fun ìti igi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú, kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye láti sọ wí pé, “Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná; Mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀, Mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí? Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”