Isaiah 44:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí, ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún, tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́: Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, ti o mọ ọ lati inu wá, ti yio si ràn ọ lọwọ; Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, iranṣẹ mi; ati iwọ Jeṣuruni ti mo ti yàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí OLÚWA wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́ láti inú ìyá rẹ wá, àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú: Má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù, ìránṣẹ́ mi, Jéṣúrúnì ẹni tí mo ti yàn.