Isaiah 44:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo ti ká àìdára rẹ kúrò bí awọsanma, mo ti gbá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ dànù bí ìkùukùu. Pada sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ pada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo ti pa irekọja rẹ rẹ́, bi awọsanma ṣiṣú dùdu, ati ẹ̀ṣẹ rẹ, bi kũku: yipada sọdọ mi; nitori mo ti rà ọ pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kùrukùru, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀. Padà sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ padà.”