Isaiah 44:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ta ni ó dàbí mi? Kí olúwarẹ̀ sọ̀rọ̀ kí ó kéde rẹ̀ níwájú mi. Ẹni tí ó bá ti kéde láti ìbẹ̀rẹ̀, nípa àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀, kí wọn sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tani yio si pè bi emi, ti yio si sọ ọ ti yio si tò o lẹsẹ-ẹsẹ fun mi, lati igbati mo ti yàn awọn enia igbani? ati nkan wọnni ti mbọ̀, ti yio si ṣẹ, ki nwọn fi hàn fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀. Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀, àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀ bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ aṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.