Isaiah 44:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Asán ni àwọn tí ń gbẹ́ ère, ohun tí inú wọn dùn sí kò lérè. Àwọn tí ń jẹ́rìí wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ nǹkan, ojú ìbá le tì wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Asan ni gbogbo awọn ti ngbẹ ere; nkan iyebiye wọn ki yio si lerè; awọn tikala wọn li ẹlẹri ara wọn: nwọn kò riran, bẹ̃ni nwọn kò mọ̀; ki oju ba le tì wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán, àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́ kò jámọ́ nǹkankan. Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú; wọ́n jẹ́ aláìmọ́kan sí ìtìjú ara wọn.