Isaiah 45:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ohun tí OLUWA sọ fún kirusi, ẹni tí ó fi àmì òróró yàn nìyí: Ẹni tí OLUWA di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, tí ó lò, láti rẹ àwọn orílẹ̀-èdè sílẹ̀ níwájú rẹ̀, láti tú àmùrè àwọn ọba, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀, kí ẹnubodè má lè tì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
BAYI ni Oluwa wi fun ẹni-ororo rẹ̀, fun Kirusi, ẹniti mo di ọwọ́ ọtún rẹ̀ mu, lati ṣẹ́gun awọn orilẹ-ède niwaju rẹ̀; emi o si tú amure ẹgbẹ awọn ọba, lati ṣi ilẹkùn mejeji niwaju rẹ̀, a ki yio si tì ẹnu-bode na;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ fún ẹni òróró rẹ̀, sí Kírúsì, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú láti dojú àwọn orílẹ̀ èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀ àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn, láti sí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.