Isaiah 45:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èmi ni mo dá ayé, tí mo dá eniyan sórí rẹ̀. Ọwọ́ mi ni mo fi ta ojú ọ̀run bí aṣọ, tí mo sì pàṣẹ fún oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo ti dá aiye, mo si ti da enia sori rẹ̀; Emi, ani ọwọ́ mi, li o ti nà awọn ọrun, gbogbo awọn ogun wọn ni mo si ti paṣẹ fun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé tí ó sì da ọmọnìyàn sóríi rẹ̀. Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run mo sì kó àwọn agbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta