Isaiah 45:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èmi ni mo gbé Kirusi dìde ninu òdodo mi, n óo mú kí ó ṣe nǹkan bí ó ti tọ́; òun ni yóo tún ìlú mi kọ́, yóo sì dá àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní ìgbèkùn sílẹ̀, láìgba owó ati láìwá èrè kan.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo ti gbe e dide ninu ododo, emi o si mu gbogbo ọ̀na rẹ̀ tọ́; on o kọ́ ilu mi, yio si dá awọn ondè mi silẹ: ki iṣe fun iye owo tabi ère, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò gbé Kírúsì ṣókè nínú òdodo mi: Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́. Òun yóò tún ìlú mi kọ́ yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.”