Isaiah 45:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, “Àwọn ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ẹrù ilẹ̀ Etiopia, ati àwọn ọkunrin Seba tí wọn ṣígbọnlẹ̀, wọn óo tọ̀ ọ́ wá, wọn óo di tìrẹ, wọn óo sì máa tẹ̀lé ọ. Wọn óo wá, pẹlu ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́sẹ̀ wọn, wọn óo sì wólẹ̀ fún ọ. Wọn óo máa bẹ̀ ọ́ pé, ‘Lọ́dọ̀ rẹ nìkan ni Ọlọrun wà, kò tún sí Ọlọrun mìíràn. Kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi, pe, Ere iṣẹ Egipti, ati ọjà Etiopia ati ti awọn ara Sabea, awọn enia ti o ṣigbọnlẹ yio kọja wá sọdọ rẹ, nwọn o si jẹ tirẹ: nwọn o tẹle ọ; ninu ẹwọ̀n ni nwọn o kọja wá, nwọn o foribalẹ fun ọ, nwọn o si bẹ̀ ọ, wipe, Nitotọ Ọlọrun wà ninu rẹ; kò si si ẹlomiran, kò si Ọlọrun miran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí OLÚWA wí nìyìí: “Àwọn èròjà ilẹ̀ Éjíbítì àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kúṣì, àti àwọn Ṣábíáṣì— wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ; wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn, wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀, wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé, ‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì sí ẹlòmìíràn; kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”