Isaiah 45:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, OLUWA tí ó dá ọ̀run. (Òun ni Ọlọrun.) Òun ni ó dá ilẹ̀, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò dá a ninu rúdurùdu, ṣugbọn ó dá a kí eniyan lè máa gbé inú rẹ̀ Ó ní, “Èmi ni OLUWA, kò sí Ọlọrun mìíràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi, ẹniti o dá awọn ọrun; Ọlọrun tikararẹ̀ ti o mọ aiye, ti o si ṣe e; o ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò da a lasan, o mọ ọ ki a le gbe inu rẹ̀: Emi ni Oluwa; ko si ẹlomiran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA wí— ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run; ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é; Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀— Òun wí pé: “Èmi ni OLÚWA, kò sì sí ẹlòmìíràn.