Isaiah 45:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N kò sọ ọ́ níkọ̀kọ̀, ninu òkùnkùn. N kò sọ fún arọmọdọmọ Jakọbu pé: ‘Ẹ máa wá mi ninu rúdurùdu.’ Òtítọ́ ni Èmi OLUWA sọ. Ohun tí ó tọ́ ni mò ń kéde.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi kò sọrọ ni ikọkọ ni ibi okùnkun aiye: Emi kò wi fun iru-ọmọ Jakobu pe, Ẹ wá mi lasan: emi Oluwa li o nsọ ododo, mo fi nkan wọnni ti o tọ́ hàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó farasin, láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn; Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jákọ́bù pé ‘Ẹ wá mi lórí asán.’ Èmi OLÚWA sọ òtítọ́; Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.