Isaiah 45:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní: “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ wá, ẹ jọ súnmọ́ bí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kù ninu àwọn orílẹ̀-èdè. Aláìlóye ni àwọn tí ń gbẹ́ ère igi lásán kiri, tí wọ́n sì ń gbadura sí oriṣa tí kò lè gbànìyàn là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ko ara nyin jọ ki ẹ si wá; ẹ jọ sunmọ tosi, ẹnyin ti o salà ninu awọn orilẹ-ède: awọn ti o gbé igi ere gbigbẹ́ wọn kò ni ìmọ, nwọn si gbadura si ọlọrun ti ko le gba ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá; ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìṣáǹṣá láti àwọn ọrílẹ̀ èdè wá. Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri, tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.