Isaiah 45:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ sọ̀rọ̀ jáde, kí ẹ sì ro ẹjọ́ tiyín, jẹ́ kí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀. Ta ló sọ èyí láti ìgbà laelae? Ta ló kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́? Ṣebí èmi OLUWA ni? Kò tún sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. Ọlọrun Olódodo ati Olùgbàlà kò tún sí ẹnìkan mọ́, àfi èmi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ sọ ọ, ki ẹ si mu wá, lõtọ, ki nwọn ki o jọ gbimọ̀ pọ̀: tali o mu ni gbọ́ eyi lati igbãni wa? tali o ti sọ ọ lati igba na wá? emi Oluwa kọ? ko si Ọlọrun miran pẹlu mi; Ọlọrun ododo ati Olugbala; ko si ẹlomiran lẹhin mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
J ẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀. Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́, ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe? Kì í ha á ṣe Èmi, OLÚWA? Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi, Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà; kò sí ẹlòmìíràn àfi èmi.