Isaiah 45:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nípa èmi nìkan ni àwọn eniyan yóo máa pé, ‘Ninu OLUWA ni òdodo ati agbára wà.’ Gbogbo àwọn tí ń bá a bínú yóo pada wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìtìjú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lõtọ, a o wipe, ninu Oluwa li emi ni ododo ati agbara: sọdọ rẹ̀ ni gbogbo enia yio wá; oju o si tì gbogbo awọn ti o binu si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú OLÚWA nìkan ni òdodo àti agbára wà.’ ” Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí; yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójú tì wọn.