Isaiah 46:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ati gbogbo ará ilé Israẹli tí ó ṣẹ́kù; ẹ̀yin tí mo pọ̀n láti ọjọ́ tí wọ́n ti bi yín, tí mo sì gbé láti inú oyún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbọ́ ti emi, iwọ ile Jakobu, ati gbogbo iyoku ile Israeli, ti mo ti gbe lati inu wá, ti mo ti rù lati inu iyá wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Tẹ́tí sími ìwọ ilé Jákọ́bù, Gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Ísírẹ́lì, Ìwọ tí mo ti gbérò láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún, tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.