Isaiah 46:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò, wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n. Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa. Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn da wura lati inu apò wá, nwọn si fi iwọ̀n wọ̀n fadaka, nwọn bẹ̀ alagbẹdẹ wura, o si fi i ṣe oriṣa: nwọn tẹriba, nwọn si nsìn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn wọ́n sì wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n; wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà, wọn sì tẹríba láti sìn ín.