Isaiah 46:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn á gbé e lé èjìká wọn, wọn á gbé e sípò rẹ̀, á sì dúró kabẹ̀. Kò ní le kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkankan. Bí eniyan bá ké pè é, kò lè gbọ́, kò lè yọ eniyan ninu ìṣòro rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn gbe e le ejika, nwọn rù u, nwọn si fi i sipò rẹ̀; o si duro: ki yio kuro ni ipò rẹ̀; nitõtọ, ẹnikan yio kọ si i, ṣugbọn ki yio dahùn: bẹ̃ni ki yio gbà a kuro ninu wahala rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n, wọ́n sì gbé e sí àye rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí. Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn; òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.