Isaiah 47:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sọ̀kalẹ̀ kí o jókòó ninu eruku, ìwọ Babiloni. Jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀, láìsí ìtẹ́-ọba, ìwọ ọmọbinrin Kalidea. A kò ní pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ ati aláfẹ́ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
SỌKALẸ, si joko ninu ekuru, iwọ wundia ọmọbinrin Babiloni, joko ni ilẹ: itẹ́ kò si, iwọ ọmọbinrin ara Kaldea: nitori a kì o pè ọ ni ẹlẹ́gẹ on aláfẹ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku, wúndíá ọmọbìnrin Bábílónì; jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ láìsí ìtẹ́, ọmọbìnrin àwọn ará Bábílónì. A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.