Isaiah 47:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ọkàn rẹ balẹ̀ ninu iṣẹ́ ibi rẹ, o ní ẹnìkan kò rí ọ. Ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ mú ọ ṣìnà, ò ń sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Èmi nìkan ní mo wà. Kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti iwọ ti gbẹkẹle ìwa buburu rẹ: iwọ ti wipe, Kò si ẹnikan ti o ri mi. Ọgbọ́n rẹ ati ìmọ rẹ, o ti mu ọ ṣinà; iwọ si ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi ni, ko si ẹlomiran lẹhin mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, ‘kò sí ẹni tí ó rí mi?’ Ọgbọ́n àti òye rẹ ti sì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi.’