Isaiah 47:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Múra sí àfọ̀ṣẹ rẹ, sì múra si oṣó ṣíṣẹ́ jọ, tí o ti dáwọ́ lé láti kékeré, bóyá o óo tilẹ̀ yege, tabi bóyá o sì lè dẹ́rùba eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Duro nisisiyi, ti iwọ ti iṣẹ afọṣẹ rẹ, ati ọpọlọpọ iṣẹ ajẹ́ rẹ, eyi ti o ti fi nṣe iṣẹ iṣe lati igba ewe rẹ wá; bi o ba ṣepe o lè jẹ erè fun ọ, bi o ba ṣe pe iwọ lè bori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo, tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá. Bóyá o le è ṣàṣeyọrí, bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.