Isaiah 47:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọpọlọpọ ìmọ̀ràn tí wọn fún ọ ti sú ọ; jẹ́ kí wọn dìde nílẹ̀ kí wọ́n gbà ọ́ wàyí, àwọn tí ó ń wojú ọ̀run, ati àwọn awòràwọ̀; tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ, nígbà tí oṣù bá ti lé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Arẹ̀ mu ọ nipa ọpọlọpọ ìgbimọ rẹ. Jẹ ki awọn awoye-ọrun, awọn awoye-irawọ, awọn afi-oṣupasọ-asọtẹlẹ, dide duro nisisiyi, ki nwọn si gbà ọ lọwọ nkan wọnyi ti yio ba ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀! Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú, Àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti oṣù dé oṣù, jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.