Isaiah 47:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Wò ó! Wọ́n dàbí àgékù koríko, iná ni yóo jó wọn ráúráú, wọn kò sì ní lè gba ara wọn kalẹ̀, ninu ọ̀wọ́ iná. Eléyìí kì í ṣe iná tí eniyan ń yá, kì í ṣe iná tí eniyan lè jókòó níwájú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiye si i, nwọn o dabi akekù koriko: iná yio jo wọn: nwọn ki yio gba ara wọn lọwọ agbara ọwọ́ iná; ẹyin iná kan ki yio si lati yá, tabi iná lati joko niwaju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lóòótọ́ wọ́n dàbí pòpó; iná ni yóò jó wọn dànù. Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là lọ́wọ́ agbára iná náà. Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná níhìnín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.