Isaiah 47:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ rí sí ọ, àwọn tí ẹ ti jọ ń ṣòwò pọ̀ láti ìgbà èwe rẹ. Olukuluku wọn ti ṣìnà lọ, kò sí ẹni tí yóo gbà ọ́ sílẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni awọn ti iwọ ti ba ṣiṣẹ yio jẹ fun ọ, awọn oniṣowo rẹ, lati ewe rẹ wá; nwọn o kiri lọ, olukuluku si ẹkùn rẹ̀; ko si ẹnikan ti yio gbà ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí gbogbo èyí ní o tí síṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀ tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀; kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.