Isaiah 47:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Inú bí mi sí àwọn eniyan mi, mo sì sọ nǹkan ìní mi di ohun ìríra. Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, o kò ṣàánú wọn. O di àjàgà wúwo rẹ mọ́ àwọn arúgbó lọ́rùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi ti binu si enia mi, emi ti sọ ilẹ ini mi di aimọ́, mo si ti fi wọn le ọ lọwọ: iwọ kò kãnu wọn, iwọ fi ajàga wuwo le awọn alagba lori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi tí mo sì ba ogún mi jẹ́; Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n. Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.