Isaiah 47:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀fọ̀ mejeeji ni yóo ṣe ọ́ lójijì, lọ́jọ́ kan náà: o óo ṣòfò ọmọ, o óo sì di opó, ibi yìí yóo dé bá ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ò báà lóṣó, kí o lájẹ̀ẹ́, kí àfọ̀ṣẹ rẹ sì múná jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nkan meji wọnyi ni yio deba ọ li ojiji, li ọjọ kan, òfo ọmọ ati opo: nwọn o ba ọ perepere, nitori ọpọlọpọ iṣẹ́ ajẹ́ rẹ, ati nitori ọpọlọpọ iṣẹ́ afọṣẹ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Méjèèjì yìí ni yóò wá sóríì rẹ láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà: pípàdánù ọmọ àti dídi opó. Wọn yóò wá sóríì rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ àti àwọn èpè rẹ tí kì í ṣélẹ̀.