Isaiah 48:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè, ọmọ bíbí inú Juda, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra, tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli, ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
GBỌ́ eyi, ẹnyin ile Jakobu, ti a nfi orukọ Israeli pè, ti o si ti inu omi Juda wọnni jade wá, ti o nfi orukọ Oluwa bura, ti o si ndarukọ Ọlọrun Israeli, ṣugbọn ki iṣe li otitọ, tabi li ododo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Tẹ́tí sí èyí, Ìwọ ilée Jákọ́bù, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Ísírẹ́lì tí o sì wá láti ẹ̀ka Júdà, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ OLÚWA tí o sì ń pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo