Isaiah 48:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo fi ta awọsanma sójú ọ̀run. Nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn jọ yọ síta.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọwọ́ mi pẹlu li o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ, atẹlẹwọ ọ̀tun mi li o si na awọn ọrun: nigbati mo pè wọn, nwọn jumọ dide duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀, àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run; nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn dìde ṣókè papọ̀.