Isaiah 48:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Gbogbo yín, ẹ péjọ, kí ẹ gbọ́, èwo ninu wọn ni ó kéde nǹkan wọnyi? OLUWA fẹ́ràn rẹ̀, yóo mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ lórí Babiloni, yóo sì gbógun ti àwọn ará Kalidea.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo nyin, ẹ pejọ, ẹ si gbọ́; tani ninu wọn ti o ti sọ nkan wọnyi? Oluwa ti fẹ́ ẹ: yio si ṣe ifẹ rẹ̀ ni Babiloni, apá rẹ̀ yio si wà lara awọn ara Kaldea.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ gbárajọ pọ̀ gbogbo yín kí ẹ sì dẹtí: Èwo nínú àwọn ère òrìṣà rẹ ló ti sọ nǹkan wọ̀nyí? Àkójọpọ̀ àwọn àyànfẹ́ OLÚWA ni yóò gbé ète yìí jáde sí Bábílónì; apá rẹ̀ ni yóò dojú kọ àwọn aráa Bábílónì.