Isaiah 48:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n, nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá, ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta, ó la àpáta, omi sì tú jáde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ongbẹ kò si gbẹ wọn, nigbati o mu wọn là aginjù wọnni ja; o mu omi ṣàn jade lati inu apata fun wọn, o sán apáta pẹlu, omi si tú jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn kọjá nínú ihà; ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta; ó fọ́ àpáta omi sì tú jáde.