Isaiah 48:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Láti ìgbà àtijọ́ ni mo ti kéde, àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀, èmi ni mo sọ wọ́n jáde, tí mo sì fi wọ́n hàn. Lójijì mo ṣe wọ́n, nǹkan tí mo sọ sì ṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi ti sọ nkan ti iṣãju wọnni lati ipilẹṣẹ; nwọn si ti jade lati ẹnu mi lọ, emi si fi wọn hàn; emi ṣe wọn lojijì, nwọn si ti ṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi sọ àṣọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́, ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mímọ̀; Lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbéṣẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.