Isaiah 48:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́: kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín, kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n, àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li atetekọṣe ni mo tilẹ ti sọ fun ọ; ki o to de ni emi ti fihàn ọ: ki iwọ má ba wipe, Oriṣa mi li o ṣe wọn, ati ere mi gbigbẹ́, ati ere mi didà li o ti pa wọn li aṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́; kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé, ‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n; àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́ sí i.’