Isaiah 48:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ ti fetí ara yín gbọ́, nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀? Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ti gbọ́, wò gbogbo eyi; ẹnyin kì yio ha sọ ọ? Emi ti fi ohun titun hàn ọ lati igba yi lọ, ani nkan ti o pamọ́, iwọ kò si mọ̀ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn Ǹjẹ́ o kò ní gbà wọ́n bí? “Láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi yóò máa sọ fún ọ nípa nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó farasin tí ìwọ kò mọ̀.