Isaiah 48:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ kò gbọ́ ọ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀. Ọjọ́ ti pẹ́ tí a ti di yín létí, nítorí mo mọ̀ pé ẹ óo hùwà àgàbàgebè, ọlọ̀tẹ̀ ni orúkọ tí mo mọ̀ yín mọ̀, láti ìgbà tí ẹ ti jáde ninu oyún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lõtọ, iwọ kò gbọ́; lõtọ, iwọ kò mọ̀; lõtọ lati igba na eti rẹ̀ kò ṣi: nitori ti emi mọ̀ pe, iwọ o hùwa arekerekè, gidigidi li a si pè ọ li olurekọja lati inu wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà. Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó; a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.