Isaiah 49:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ọ̀run kọrin ayọ̀, kí ayé kún fún ayọ̀, ẹ̀yin òkè, ẹ máa kọrin, nítorí, OLUWA ti tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu, yóo ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀ tí ìyà ń jẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kọrin, ẹnyin ọrun; ki o si yọ̀, iwọ aiye; bú jade ninu orin, ẹnyin oke-nla: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, yio si ṣãnu fun awọn olupọnju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ hó fún ayọ̀, Ẹ̀yin ọ̀run; yọ̀, ìwọ ilẹ̀-ayé; bú sórin, ẹ̀yin òkè-ńlá! Nítorí OLÚWA tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú.