Isaiah 49:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbójú sókè, kí o wò yíká, gbogbo àwọn ọmọ rẹ péjọ, wọ́n tọ̀ ọ́ wá. OLUWA fi ara rẹ̀ búra pé, o óo gbé wọn wọ̀ bí nǹkan ọ̀ṣọ́ ara. O óo wọ̀ wọ́n bí ìgbà tí iyawo kó ohun ọ̀ṣọ́ wọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbe oju rẹ soke yika kiri, si kiyesi i: gbogbo awọn wọnyi ṣà ara wọn jọ, nwọn si wá sọdọ rẹ. Oluwa wipe, Bi mo ti wà, iwọ o fi gbogbo wọn bò ara rẹ, bi ohun ọṣọ́, nitõtọ, iwọ o si há wọn mọ ara, bi iyawo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbójú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká; gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè,” ni OLÚWA wí, “Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́; ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.