Isaiah 49:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Dájúdájú ilẹ̀ rẹ tí ó ti di aṣálẹ̀, ati àwọn tí ó ti di ahoro, yóo kéré fún àwọn tí yóo máa gbé inú rẹ̀ tí ó bá yá, a óo sì lé àwọn tí ó pa ọ́ run jìnnà sí ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ibi ofò rẹ, ati ibi ahoro rẹ wọnni, ati ilẹ iparun rẹ, yio tilẹ há jù nisisiyi, nitori awọn ti ngbe inu wọn, awọn ti o gbe ọ mì yio si jinà rére.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìgbòrò, ní ìsinsìn yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ti ó jẹ ó rùn ni yóò wà ni ọ̀nà jínjìn réré.