Isaiah 49:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ tí o bí ní àkókò ìgbèkùn rẹ yóo sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ pé, ‘Ibí yìí kéré jù fún wa, fún wa ní àyè sí i láti máa gbé.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ-ọmọ rẹ ti o ti nù yio tun wi li eti rẹ pe, Ayè kò gbà mi, fi ayè fun mi lati ma gbé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ, ‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa; ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’