Isaiah 49:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O óo bèèrè lọ́kàn ara rẹ nígbà náà pé, ‘Ta ni ó bí àwọn ọmọ wọnyi fún mi? Ṣebí àwọn ọmọ mi ti kú, mo ti yàgàn, mo sì lọ sí ìgbèkùn lóko ẹrú. Ta ni ó wá tọ́ àwọn wọnyi dàgbà? Ṣebí èmi nìkan ni mo ṣẹ́kù, níbo ni àwọn wọnyi ti wá?’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni iwọ o wi li ọkàn rẹ pe, Tali o bi awọn wọnyi fun mi, mo sa ti wà li ailọmọ ati li àgan, igbèkun ati ẹni-iṣikiri? tani o si ti tọ́ awọn wọnyi dagba? Kiyesi i, a fi emi nikan silẹ, awọn wọnyi, nibo ni nwọn gbe ti wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘ta ló bí àwọn yìí fún mi? Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn; A sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀. Ta ló wo àwọn yìí dàgbà? A fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”