Isaiah 49:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, “Wò ó, n óo gbé ọwọ́ mi sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè. N óo gbé àsíá mi sókè sí àwọn eniyan, wọn óo gbé àwọn ọmọ rẹ ọkunrin mọ́ àyà wọn wọn óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin sí èjìká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa Jehofa wi, Kiyesi i, emi o gbe ọwọ́ mi soke si awọn Keferi, emi o si gbe ọpágun mi soke si awọn enia, nwọn o si gbe awọn ọmọkunrin rẹ wá li apa wọn, a o si gbe awọn ọmọbinrin rẹ li ejìka wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí níyìí: “Kíyèsí i, Èmi yóò késí àwọn aláìkọlà Èmi yóò gbé àṣíá mi ṣókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn; Wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní èjìká wọn.