Isaiah 49:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọba ni yóo máa tọ́jú rẹ bíi baba, àwọn ayaba yóo sì máa tọ́jú rẹ bí ìyá, ní ìdojúbolẹ̀ ni wọn óo máa tẹríba fún ọ, wọn óo sì máa pọ́n eruku ẹsẹ̀ rẹ lá. O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA, ojú kò ní ti àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọba yio jẹ baba olutọju rẹ, awọn ayaba wọn yio si jẹ iya olutọju rẹ; ni idojubolẹ ni nwọn o ma tẹriba fun ọ, nwọn o si lá ekuru ẹsẹ rẹ; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa; nitori oju kì yio tì awọn ti o ba duro dè mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́-baba fún ọ, àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́. Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀; wọn yóò máa lá èrùpẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA; gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi ni a kì yóò jákulẹ̀.”