Isaiah 49:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní: “Bí ó bá tilẹ̀ ṣeéṣe láti gba òǹdè lọ́wọ́ alágbára, tabi láti gba ìkógun lọ́wọ́ òkúrorò eniyan. N óo bá àwọn tí ó ń bá ọ jà jà, n óo sì gba àwọn ọmọ rẹ là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bayi ni Oluwa wi, a o tilẹ̀ gbà awọn ondè kuro lọwọ awọn alagbara, a o si gbà ikogun lọwọ awọn ẹni-ẹ̀ru; nitori ẹniti o mba ọ jà li emi o ba jà, emi o si gbà awọn ọmọ rẹ là.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ohun tí OLÚWA wí níyìí: “Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbékùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun, àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú; Ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà, àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà.