Isaiah 49:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo mú kí àwọn tó ń ni ọ́ lára máa pa ara wọn jẹ: wọn óo máa mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn, bí ẹni mu ọtí, gbogbo ayé yóo sì mọ̀ nígbà náà pé, èmi ni OLUWA, Olùgbàlà rẹ, Olùràpadà rẹ, Ọlọrun alágbára Jakọbu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti o ni ọ lara li emi o fi ẹran ara wọn bọ́, nwọn o mu ẹjẹ ara wọn li amuyo bi ọti-waini didùn: gbogbo ẹran-ara yio si mọ̀ pe, Emi Oluwa ni Olugbala ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara ti Jakobu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ ẹran ara wọn; wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹnii mu wáìnì. Nígbà náà ni gbogbo ọmọnìyàn yóò mọ̀ pé Èmi, OLÚWA, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kanṣoṣo ti Jákọ́bù.”