Isaiah 49:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn mo dáhùn pé, “Mo ti ṣiṣẹ́ àṣedànù. Mo ti lo agbára mi ṣòfò, mo ti fi ṣe àṣedànù, sibẹsibẹ ẹ̀tọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ OLUWA.” Ẹ̀san mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọrun mi, yóo san án fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo wi pe, Emi ti ṣiṣẹ́ lasan, emi ti lò agbara mi lofo, ati lasan: nitõtọ idajọ mi mbẹ lọdọ Oluwa, ati iṣẹ mi lọdọ Ọlọrun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n èmi ṣọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán; mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀ mófo. Síbẹ̀ síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sími sì wà lọ́wọ́ OLÚWA, èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”