Isaiah 49:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nisinsinyii, OLUWA, tí ó ṣẹ̀dá mi ninu oyún, kí n lè jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, láti mú Jakọbu pada tọ̀ ọ́ wá, ati láti mú kí Israẹli kórajọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí mo níyì lójú OLUWA, Ọlọrun mi sì ti di agbára mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nisisiyi, li Oluwa wi, ẹni ti o mọ mi lati inu wá lati ṣe iranṣẹ rẹ̀, lati mu Jakobu pada wá sọdọ rẹ̀, lati ṣà Israeli jọ, ki emi le ni ogo loju Oluwa, Ọlọrun mi yio si jẹ́ agbara mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí OLÚWA wí pé ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú Jákọ́bù padà tọ̀ mí wá àti láti kó Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú OLÚWA Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi