Isaiah 49:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun, láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ. Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè kí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, O ṣe ohun kekere ki iwọ ṣe iranṣẹ mi, lati gbe awọn ẹyà Jakobu dide, ati lati mu awọn ipamọ Israeli pada: emi o si fi ọ ṣe imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le ṣe igbala mi titi de opin aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun wí pé: “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti mú ẹ̀yà Jákọ́bù padà bọ̀ sípò àti láti mú àwọn ti Ísírẹ́lì tí mo ti pamọ́. Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá sí òpin ilẹ̀ ayé.”