Isaiah 49:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà Israẹli, ati Ẹni Mímọ́ rẹ̀, sọ, fún ẹni tí ayé ń gàn, tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìíra, iranṣẹ àwọn aláṣẹ, ó ní, “Àwọn ọba yóo rí ọ, wọn óo dìde, àwọn ìjòyè yóo rí ọ, wọn óo sì dọ̀bálẹ̀. Nítorí OLUWA, tí ó jẹ́ olódodo, Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ti yàn ọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa, Olurapada Israeli, ati Ẹni-Mimọ rẹ wi, fun ẹniti enia ngàn, fun ẹniti orilẹ-ède korira, fun iranṣẹ awọn olori, pe, Awọn ọba yio ri, nwọn o si dide, awọn ọmọ-alade pẹlu yio wolẹ sìn, nitori Oluwa ti iṣe olõtọ, Ẹni-Mimọ Israeli, on li o yàn ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí OLÚWA wí nìyìí Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì— sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kóríra lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀ èdè, sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ: “Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè, àwọn ọmọ ọba yóò ríi wọn yóò sì wólẹ̀, nítorí OLÚWA ẹni tí í ṣe olótìítọ́, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tí ó ti yàn ọ́.”