Isaiah 49:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo dá ọ lóhùn, lọ́jọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́. Mo ti pa ọ́ mọ́, mo sì ti fi ọ́ dá majẹmu pẹlu àwọn aráyé, láti fìdí ilẹ̀ náà múlẹ̀, láti pín ilẹ̀ tí ó ti di ahoro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa wi, Li akoko itẹwọgba emi ti gbọ́ tirẹ, ati li ọjọ igbala, mo si ti ràn ọ lọwọ: emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, lati fi idi aiye mulẹ, lati mu ni jogun ahoro ilẹ nini wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí OLÚWA wí nìyìí: “Ní àkókò ojú rere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,