Isaiah 5:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ kutukutu, láti máa wá ọtí líle kiri, tí wọ́n ń mu ún títí di ìrọ̀lẹ́, títí tí ọtí yóo fi máa pa wọ́n!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Egbe ni fun awọn ti ima dide ni kùtukutu, ki nwọn le ma lepa ọti lile; ti nwọn wà ninu rẹ̀ titi di alẹ, titi ọti-waini mu ara wọn gbona!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti lépa ọtí líle, tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́ títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.