Isaiah 5:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dùùrù, hapu, ìlù, fèrè ati ọtí waini wà níbi àsè wọn; ṣugbọn wọn kì í bìkítà fún iṣẹ́ Ọlọrun, wọn kìí sìí náání iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati durù, ati fioli, tabreti, ferè, ati ọti-waini wà ninu àse wọn: ṣugbọn nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, bẹ̃ni nwọn kò rò iṣẹ ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ní hápù àti láà níbi àṣè wọn, tamborínìn òun fèrè àti wáìnì, ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ OLÚWA sí, kò sí ìbọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.